igbeyawo wa lara re.
Gbogbo eto lesese la ma menu baa.
1.IFOJUSODE
Nigba ti odomokunrin kan ba ti balaga, awon obi re yoo ti bere si fi oju sile boya nwon a le ri omobinrin kan tin won yoo fe fun omo won.Omokunrin yi paapaa laije pe enikeni so fun un,yoo bere si se finnifinni ju ti ateyinwa lo; yoo we nigba meta loojo, yoo toju eyin, enu,eekanna owo ati tese, gbogbo ara yoo si maa jolo. Ni kete ti okunrin ba fi oju kan wundia
(omobinrin ti ko ti mokunrin) ti o je oju ni
gbese, ise wa di ti alarina.
2.ALARINA
Alarina ni eni ti o ngbokegbodo laarin
omokunrin ati omobinrin ti wo ba ni ife si ara won. Awon obinrin lo saba maa nsise yi daradara. Ise alarina ni lati wa idi ohun gbogbo kinnikinni nipa omobinrin yi. Idi re ti a fi nwa idi ni wipe ko si eni ti yoo fe gbe eni ti won n dete ni idile won, tabi iran asinwin, tabi obinrin onijagidijagan ni iyawo. Ise alarina ni lati pon ati latI ge omokunrin yi loju omobinrin ki o si la oju agi si agi (yoo seto bi omokunrin
yoo se pade omobinrin).
3.ISIHUN TABI IJOHEN
Leyin igba ti alarina ba ti la oju awon mejeeji kan ara won, omokunrin ati omobinrin yi yoo bere si pade ni orisirisi ibi (labe igi odan nigba osupa, ni eyin ilea won omobinrin). Leyi igba ti won ba ti se eleyi fun igba pipe, omobinrin yoo wa je hoo fun lati gba beni yoo sofun omokunrin ki o seto bi baba ati iya oun yoo se gbo nipa ore won. Gbigba ti omobinrin gba yi ni awa Yoruba npe ni Ijohen tabi Isihun .
4.ITORO
Leyin igba ti omobinrin ba ti juwo sile patapata, omokunrin yoo lo so fun baba re pe oun ti ri ododo kan ti o pupa, ti o si lewa ni ile Lagbaja tabi Lakasogbe ti oun fe ja. Baba re yoo wa bi lere boya ododo naa yoo see ja tabi ko ni see ja.
Omokunrin naa yoo wa so gbogbo adehun ti oun ati omobinri yi ti se fun ara won. Eyi ni yoo fun baba re ni anfani lati lo baa won agbaagba adugbo re soro gegebi won yo se lo toro omo.
Ni igba kini tin won yoo lo ri baba omobinrin,baba omokunrin ati omo ile kan tabi meji ni yoo lo. Owuro kutu hai ni nwon si maa nrin iru irin yi. Nwon o ko, nwon yoo soro fun baba omobinrin. Oro yi ko ni je kayefi si baba omobinrin yi notori o ti bere si ri irin ese omo re. Idahun ti baba yi yoo si fun awon wonyi nipe kii se oun nikan lo bimo yi ati pe kin won wa pade molebi oun ni ojo bayibayi.
5.IDANA
Leyin igba ti won ba ti toro omo tan,idana ni gbogbo won yoo fi okan si. Gbogbo awon ti o ye kin won gbo nipa itoro ti nwon ko gbo, ati gbogbo awon ti o gbo ti won ko ri aye lo, akoko niyi lati fi owo si. Awon idile mejeeji yoo ranse si awon eniyan won nibikibi ti nwon ba wa.
Idana yi se Pataki pupo nitori ibe ni awon idile mejeeji ti maa npade lekunrere. Ni ojo idana yi awon iyawo baba omobinrin ati iyawo baba omokunrin yoo pagbo ere, olukuluku won yoo maa ki oko won. Owuro kutukutu tabi irole patapata ni a nse idana. Lati ile omokunrin ni nwon ti maa ru gbogbo ohun idana wa.
6.AWON OHUN IDANA
Oyin, ireke ati iyo – eyi nip e aye won a dun;obi ati orogbo- eyi nip e nwon yoo gbo (dagba),atare- eyi nip e iyawo yoo bimo pupo; epo- eyi ni wipe yoo de won lara. Leyin eyi ni nwon yoo waru opolopo emu ati opolopo oti oyinbo fun mimu awon ti o wa sibi aseye naa. Gege bi asa
Yoruba, eni ti o dagba ju nile iyawo yi ni yoo fa iyawo le eni ti o dagba ju ni ile oko lowo. Yoo sika awon iba die funn alagba yipe nwon kii na omo won; ebi kii pa, kii je gbaguda (ege) ati beebee lo.
7.IPALEMO
Eyi tio ku ni ki iyawo maa pa ile re mo diedie leyin ti won ti dana tan. Ona meji ni oko iyawo le gba lati ran iyawo re lowo lati palemo.
Ona kini, oko iyawo le fun iyawo re ni owo lati pese aso ati yeti ti yoo maa lo ni ile oko. Ona keji ni ki oko be eniyan fun ara re lati ra gbogbo awon nkan wonyi, ki o si lo gbe e fun iyawo re lodidi.
8.IGBEYAWO
Igbeyawo ma nyato lati agbegbe si agbegbe; lati ilu kan si ilu keji ati lati ileto si ileto. Sugbon,awon nkankan wa ti o je pe ko le yato niwon igba ti o ba ti je ile Yoruba ni a ti n se igbeyawo naa. Ni oju ale patapata ni iyawo maa nlo si ile
oko re. Ni ojo igbeyawo yi, ati ile iyawo ati ile oko, ojo ti o yato ninu ojo nii se.
Nigba ti iyawo ba fe kuro ni ile awon obi re,gbogbo awon obi re ati awon ibatan obi re ni yoo pejo. Olori idile won ni yoo si saaju lati gbadura fun iyawo naa pelu omije loju, iyawo naa yoo maa se amin pelu omije, gbogbo ile a si maa gbadura fun omidan yi leselese pelu omije.
Yoruba ma n pe ekun ti awon to n gbadura funiyawo n sun ni isun idagbre ti won si ma n pe ekun ti iyawo nsun ni ekun iyawo.
Nigba ti iyawo ba ti nsunmo ile oko re, oko re gbodo jade ni ile nitori eewo ni ni ile Yoruba ki iyawo ba oko re ni ile. O je asa ni awon agbegbe kan lati pa ohun eleje si ese iyawo ki o to wo ile oko re. Sugbon ki iyawo to wo ile oko re ni awon agbegbe miran, a gbodo fi omi we ese re ni enu ona. Nigba ti iyawo ba wole gbara, odo olori idile ni nwon yoo muu lo. Ibe
ni a o ti sure fun un.
Asa Yoruba ni ki oko sunmo iyawo re ni ale ojo keta lati mo boya o ti mo okunrin kan tele tabi ko mo okunrin rara. Ti iyawo ba ti mo okunrin,
oro itiju patapata ni fun ohun ati molebi re, paapaa julo iya re. Sugbon bi iyawo ko ba ti mo okunrin kan tele, gbara ti oko iyawo ti se tan ni ariwo yoo ti so ni ile won. Awon ara ile won yoo si ko ere lo si ile baba iyawo ti won yoo si maa sajoyo pe awon ba omo won nile.
This post simply talks about Marriage rites in the Olden days.........
Eto igbeyawo laye, oba Oluwa lo fi le le pelu ase ni.
ReplyDeleteπΌπΌπΌπΌπΌ
DeleteEkaro, Ekasan Nile ooo
ReplyDeleteEmabinu pe o gun gan
Moki gbogbo awon musulumi ododo,ku odun
Emi yi o shey opolopo
Oya eje ka fi oro jomi toro oro
Olorun afi ibukun si gbogbo igbeyawo
ReplyDeleteAmin oo
DeleteKam biakwanu.( I dey come) @Princess Tever
ReplyDeleteBia osiso πππ
DeleteThat chair is all I see.. LMAO ππππππππππ
ReplyDeleteπππππ
DeleteEto igbeyawo a maa dun ni aye atijo. Gbogbo yamayama ti mo n ka nipa kosiini (cousin) ti wo n fe ara won ko le shele lai lai.
ReplyDeleteOrisirisi anfaani ni o wa nine. Sugbon, olaju ti ba aye je, civilization ti pa pupo ninu asa wa.
Olori Orente, e ku ise takuntakun. Ire o!!!!
Oro kosini yen o ma nisosi
DeleteOmo iyaπππππ
olori Ku ise opolo, sugbon apoti iyanu Yi ga gan o
ReplyDeleteπππππ
DeleteEku ise opolo o. Eto igbeyawo ni aye atijo je oun to awon eniyan ponle gidigan,ko da bi aye ode oni ti won ti so o di idakuda.
ReplyDeleteBeeni
DeleteOmo this one gidigan, igeyawo je ohun nla ni ile yoruba, I pray goodness and favour into every marriages IJN
ReplyDeleteAminπππ
DeleteOlori Orente, eni iyi, eni eye. E ku ise opolo oh. Ibeere temi ni wipe, Se ni ile Yoruba nikan ni a ti n se akiyesi awon asa igbeyawo yi ni abi ni ile gbogbo eleya dudu ni? ati wipe kini ibale obirin niise pelu ibagbe ati ibalopo pelu oko re leyin igbeyawo laye atijo?
ReplyDeleteOmo iya, ile yoruba ni atin shey igbeyawo eleyi
DeleteNitori Yoruba MA n Gbe asa igbeyawo laruge
Nipa ibale iyawo, iya MI fi yemi wipe obinrin ti won ko baba nile laye igbayen koni iyi rara.
Sugbon olaju tiyi nkan pada.