Stella Dimoko Korkus.com: ORIKI NI ILE YORUBA

Advertisement

Wednesday, November 08, 2017

ORIKI NI ILE YORUBA

Kilo shele?Ema bo,je ka ko yoruba....Emi ni Stella.mon ko intro...Hahahahahahahahahahahhaha





Oriki je asa kan ti o je iran Yoruba l’ogun pupo, eyi si mu won yato si awon iran yoku patapata, ko si ojulowo omo kaaro- o- o- jiire , ti ko ni oriki, yala oriki orile ni tabi oriki idile ati paapaa oriki oruko.Oriki je awon oro isiri ti awon Yoruba maa n fi yin ara won tabi eni ti inu won ba dun si.


Orisirisi iran ti won maa n ki ojulowo omo Yoruba mo niwonyi; iran Alaran, Aagberi, Olu-oje, Osulakesan, Ijamogbo, Onikoyi, Oko irese, Ajisola, Ologbin-in, Opomulero, Olofa, Olokun-Esin, Olufe, Elerin, Ijese, Iloko, Orin, Aresa.
Oriki orile ni ewi alohun ti o n so nipa itan awon baba nla eni ni ile Yoruba, idile ti won ti se wa,orirun iran, ise akin ti won ti gbe ile aye se, ise iran naa ati beebee lo.


Oriki idile a maa so nipa irisi iran, isesi, eewo iran, ise iran, aleebu iran ati beebee lo.


Oruko oriki ni oruko keji ti awon Yoruba maa n fun omo ni ojo isomoloruko yala okunrin tabi obinrin bi apeere;
Ajoke, Amope, Isola, Atoke, Ajao, Arike, Abike, Ajani .Aimoye awon omo wa in won ko ni oruko oriki mo ti kosi daara.


Daruko orike re .


Bv Olori Orente

66 comments:

  1. Hahahaha
    Stella funrare,obirin bi okunrin
    Oriki WO in ka fun Stella ooo

    ReplyDelete
    Replies
    1. I no fit cum give mysef headache.


      Bounce out of post👟👟👟👟👟

      Delete
    2. Arike ni oriki Stella Lati eni lo

      Delete
    3. Opómúléró mo jaàlekàn
      Òpó róso, òpó bàjá
      Omo Oníkòyí,
      Ìkòyí èsó ni pelemo,
      Lójú Ogun.

      Delete
    4. Ìdílé ìyá

      Ìsàgá òkunmàsè
      Ahéré owó ò ní gbàgede
      Omo abéré méta,
      Òkán se, òkán nù.
      Òkan yóku la fi n rángba aso
      Omo Oba Séru.

      I've always been warned never to tell people my oríkì name anyhow because of spiritual connotations.

      Olorì Òrenté, e kú isé opolo.

      Delete
  2. Ek'aro.

    Emi Omo Igbo.

    Mi o bo..

    Olori Orente ewa explain.

    ReplyDelete
    Replies
    1. Chike bawoni
      Ti oba ti ma komi ni IGBO,ma ko e ni yoruba

      Delete
    2. Olori Orente, mi ofe eleyi ooo.
      Kini gbogbo eleyi?
      Ewa clear me, you carry more confusion gimme.
      😂😂😂😂

      Delete
    3. Lol......Chike biko fimile ooo

      Delete
  3. Bawaoni?

    Shotigbo?

    Olaniyi

    Yemisi..Lol

    ReplyDelete
  4. Hahahaha deola 9c one o

    Oriki yi mu mi ranti iya iya mi (olorun a tun bo ma bami te si afefe we)

    ReplyDelete
    Replies
    1. Emi na ranti iya baba mi ni oooo
      Orun re, OMA kimi titi,
      Abike

      Delete
  5. Replies
    1. Oriki temi nje arike mosi ranti iya to bi iya mi maa n pe mini arike ikan ninu awon oluko mi maa n pe mini ariyike

      Delete
  6. E ku ise opolo,e ku aigbagbe. Arinke l'oriki t'emi o. A de maa nki idile wa ni Omo"Olufe". E ku ise takuntakun o. Oodua a gbe wa o😁

    ReplyDelete
  7. Amope Okin Omo Olofa mojo.

    Omo abisu joruko, ijakadi loro ofa.
    Omo ijakan ti won jaa l'Ofa lojosi.
    Molose oju kini? Ose oju poro loko, osoju agbele yaraara. Iba soju Oloko Iba lawon. Omo buu re, laare, okan ogbodo jookan. Tori bokan ba jokan lo no ile Olalomi, ogun nii kowan roro. My Town (Offa, Kwara State) has got to have the most popular Oriki of them all.
    #UmmuKam

    ReplyDelete
  8. oriki baba mi ni ogogo òmò kulodo. mi o mó oriki temi sugbon olomi ni òkò mi maa n pemi.

    ReplyDelete
  9. Arike ni oriki to e mi Na ...emi omo opomulero mojalekan opo roso opo panja

    ReplyDelete
  10. Arike ni oriki mi, Olori Orente o ko so oriki re funwa o... Bawo ni gbogbo nkan, se ise nlo deede... O gbiyanju fun eyi ti o se yi o.. Gba ikonu (kisses) ife..

    ReplyDelete
    Replies
    1. Omo iya mi
      Abike ni oriki temi
      Adupe ooo,ao se are

      Ikonu Ife temi naa

      Delete
  11. Abike [Ìyá mi]
    Ajoke [èmi]
    Atoke [Omo mi]

    ReplyDelete
    Replies
    1. Abike lemi
      Arike Aburo mi
      Alamu Aburo mi

      Delete
  12. Emi ni Adunni, omo Arulogun bi eefi; omo o'shoro da egberun eshinshin bora; omo oko isu si aja ki aja ro giirigi, omo ara oko ko gbodo she bi ara ile!!!


    Arulogun fihan wipe jagunjagun ni awon iran Baba to bi mi l'omo


    Osh'oro da egberin ashinshin bo'ra- ni ojo pipe, Ogun ni won bo ni idile wa, bi won ba ti be ori aja si Ogun tan, eni ti o be a ro eje ori aja naa si ori ara re ki o to fi ori aja naa si'di Ogun. Eshinshin a maa kun onitohun nitori eje aja yi, ti o fa oriki "osho'ro da egberun eshinshin bora"


    "Oko isu si aja ki aja ro giiriri"- Nigba ti ko ba si ogun, awon Baba Baba mi a ma shishe agbe, won si je akikanju ni idi she yi, isu won maan ta daada, idi ti won fi n ki wa bee niyi.


    Toor, labare lara oriki ara mi ati idile niyi, owo n ro mi, mo fe sinmi.


    Bi a ba ri eni ti o le ka, ti otun le tunmo ohun ti mo ko si ede geesi to dangajia, mo pinu egberun mewa naira fun eni bee.


    Nitooto, ede Yoruba dun!





    SHARONNA

    ReplyDelete
    Replies
    1. Adunni oriki re dun gan ooo
      Aku igbe ede wa laruge

      Delete
    2. Let me try to interprete...oshoro da egberin esinsin bora...long ago your forefathers were warriors and they worshipped Ogun...when sacrificing to Ogun, (dogs were used) the executioner or beheaded will behead the dog and pour the dog's blood on his own head, after which he will lay the dog's head at Ogun's shrine. Due to the blood on his head, houseflies will be attracted to it hence the accolade...he covers himself with a thousand flies.
      Oko isu so aja, ki aja to giiriri...this means that in the absence of war or at the time of peace, your ancestral fathers will take up farming. They were so hardworking and dedicated that the products (mainly yam) were robust and fruitful. This birthed the title.
      Omo oko ko gbodo se bi ara ile...loosely this means that the villager must not behave like the townsmen. This means that one should be true to who he is and not pretend to be someone else. Originality is important
      Looto ede Yoruba fun poo
      Hope my 'geesi' was 'dangajia' enough?
      Yours truly
      Toyobaby

      Delete
  13. O ku òpòló..... oriki mi ni Asábì. Iya mi lo funmi ni oriki yii nitori wipe Asabì ni oruko iya won.
    Tì olowo orì mi bati se mi,ti o si fe bèbè ti o ba ti kìì mi daada pelu oriki mi, orimi asi maa wu bi gaari ifò😁😁...Ija ti pari niyen.

    ReplyDelete
    Replies
    1. A won okunrin mo yi oriki yii gidigan ni, oko mi a ma SAA mi to ba fe GBA nkan lowo mi.

      Delete
    2. Bi oko mi na shey ma n mu Simi Lori niyen

      Delete
  14. Emi omoyeleru,omo asowola gbendeke, omo olobo NLA isiwo tofiberu to fi bimo tofibi olori lafin Oba. Omo Petu ado, omo aimarasa Omo lukere ogboye gbokogbaila.

    ReplyDelete
  15. Emi omoyeleru,omo asowola gbendeke, omo olobo NLA isiwo tofiberu to fi bimo tofibi olori lafin Oba. Omo Petu ado, omo aimarasa Omo lukere ogboye gbokogbaila.

    ReplyDelete
  16. Shey dada le wan?
    Awon omo nkan o

    Odabo o😂😂😂

    ReplyDelete
  17. Ayinke no oriki ti e mi. Omo Ede ni iya mi. Awon ni won ma n ki wipe "Opomulero moja alekan omo esu. Opo ro so. Opo gba ja.Baba mi je omo ilu Eko, Awon ni won ma ki ni "Eko aro mi sa legbelegbe.Mo so tun fe omo Ibadan, Ibadan ni ile oluyole,nibi Ole gbe n jare olohun. Olori Orente e ku ise opolo, a ma ju yin se o.Amin

    ReplyDelete
  18. Emi Abebi
    Omo olokun seri ade
    Omo arije sopo ile
    Omo olokun ajifiluki
    Omo olokun aji fi eran nla bo
    Omo olokun agana erin
    Erin beji oyaso
    ....
    #mumisaac

    ReplyDelete
  19. Bawo ni
    Ema bi nu
    E' Pele

    Hope my Yoruba is on point @ olori orente.

    ReplyDelete
  20. E mi o ki'n se omo yoba amo mogbo yoba di e.

    Oko mi ma npe mi ni morenikeji, eni keji mi, eni ti okan mi fe.

    Olori Orente gbayi!

    ReplyDelete
    Replies
    1. Awwwe iyen na dun oooo
      Cynthia monife bi ESE gbo Yoruba yen

      Delete
  21. Olori omo'dada!

    Omo'to fine!

    Ekun'gbadun!

    Eka'ro

    Ese'un oh

    Alafia alafia

    Oda'bo

    ReplyDelete
  22. @ Arabirin Sharonna, itumo yoruba ti e ko ni ede geesi lo bayii." I am Adunni,the child of the one that is fierce in battle like smoke. The child of Osh'oro who is covered with a thousand flies. The child of one who keeps yams in the barn till it becomes mighty. The child of one who is an indigene that must not behave like an outsider. Arulogun means that my father's ancestors were mighty warriors Osh'oro who is covered by a thousand flies. A long time ago, my family were "Ogun" worshippers, During the festival of Ogun worship, the person that cuts off the head of the dog used in the worship will pour the blood coming out of the head of the dog on his own head before dropping the head of the dog at the shrine of Ogun,The head cutter becomes covered with flies due to the blood he has poured on his head hence the praise Osh'oro coverd in a thousand flies. The one who puts yam in the barn till it becomes mighty. When there is no war, my forefathers are farmers and they are hard working when it comes to farming so they do have a bountiful harvest.Because they harvest big yams hence the praise of having a mighty barn.
    Translation by The Girl

    ReplyDelete
  23. Nle Oooooo Omo Alagbe Nwa Jegbin Jora.Jegbin Jora Kole Joye Pe Ni Won Ki Iba Aron Mu Onshile Iba Aran Mama Dahun.Iba Alaka Loko Iba Gbedudu Maro, Ole Kati Odo Ojojo. Ojojo Iba Shole Kon ton Logun Odun Niwon Ki Ba Aronmu Ohunshile. Oriki Idile Baba Mi Re Ni ILE-OGBO NI OSUN OSHOGBO.Opo Ju Bayi Lo Mo Ko Ni Ki Fun Yin Ni Tansho Ni Nu E Ni.

    ReplyDelete
  24. Emi ni iloti, Omo agbo, Omo oloti subu, Omo oloti ape, Omo oloti to subu mati di de

    ReplyDelete
  25. Emi ni Abike, Omo Ikoyi Eso...

    ReplyDelete
  26. Olori Orente e ku ise opolo oh!
    Oriki mi ni Awero okin, emi ni omo Ibadan n' le Oluyole,
    nibi ole gbe n jare olohun.Maja maja ni ti Ibadan to fi ko ara iwaju leru.
    Ibadan ilu t'Ojo, ilu T'aJADI, ilu OGUNMOLA .
    Asabi, Asake ati Apeke ni oriki awon omo mi.
    Oke Ibadan a gbe wa lagbara eje Jesu kiristi.AMIN.
    MO gbe osuba nla fun @ the grey goose and @ife4ril!
    e ku ise opolo fun itumo geesi ti e se fun oriki yen.

    ReplyDelete
  27. E jowo,Eso oriki Ota fun mi ni kikun.

    ReplyDelete
  28. Aku ojumo ooo edakun e so oriki ajadi funmi ni kikun

    ReplyDelete
  29. Abike lemi, oloye layangi oyinlola omo asao
    Adunni mummy mi
    Arike egbon mi
    Ajao daddy mi

    ReplyDelete
  30. oriki orile ti mo bere mi o RI

    ReplyDelete

Disclaimer: Comments And Opinions On Any Part Of This Website Are Opinions Of The Blog Commenters Or Anonymous Persons And They Do Not Represent The Opinion Of StellaDimokoKorkus.com

Pictures and culled stories posted on this site are given credit and if a story is yours but credited to the wrong source,Please contact Stelladimokokorkus.com and corrections will be made..

If you have a complaint or a story,Please Contact StellaDimokoKorkus.com Via

Sdimokokorkus@gmail.com
Mobile Phone +4915210724141